Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, mogbaladura laaro yi wipe eledumare koni jeki enikookan wa jaye inira loni ase.
Laaro yi mo nfe ki a mo iwulo ewe to wa ninu aworan yi ninu odu ifa EJIOGBE, atiwipe bi mo se maa nso tele wipe ise babalawo ki nse ki a maa ki orefe ifa tabi ka maa peran je lasan, a gbudo mo sise ati awon nkan to je opomulero to gbe ifa duro katole maa pera wa ni babalawo, opolopo lo maa nko ifa sita to je wipe orefe ifa lasan ni ti ko kun oju iwon tosi jasi wipe awon ogberi yio ro wipe ifa gidi ni.
Ifa naa ki bayi wipe:
Arogbodo lefo
Èròwòò niti tete
Ki aye ele kuro lode
Erowoo loku a difa fun baba ajero majele lojo ti nfojojumo njaye ele sugbon ti yio pada jaye irorun won ni ko karaale ebo ni ki o wa se ki o baa le jaye ero, obi meji, agba elede, igbin, ose dudu ati igba ewe ayajo ifa pelu ewe to wa ninu aworan yi, baba kabomora o rubo won se sise ifa fun, lati igba naa ni baba ko wa jaye ele mo aye ero lo bere sini je, o wa njo o nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni nje riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa.
O wa fiyere ohun bonu wipe:
Igba odundun o
Igba tete
Igba worowo
Oni ni ode a dero o
Nje igbin mi de omo elero akoko pero sawo nile pero sawo lona, igbin ko ma nile olojò nwo o.
Leyin igbati a ba bo ifa tan ni ao gun awon ewe ifa naa pelu awon elo toku pelu ose ti ao wa gbaye ifa yi si ose naa ti akapo naa yio maa fiwe, kosi eniti o ba nlo ose ifa yi to le ri inira laye, koda ibi, ofo, ibanuje tabi ajogun ibi kankan koni le wole too beeni koni dubule aisan.
Eyin eniyan mi, mogbaladura laaro yi wipe ajogun buburu koni wole towa o, eledumare yio so igba inira aye di ero pese, ako ni ku sinu inira yi o lenu ibiti odun yi kusi ako ni dubule aisan o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO
Lati owo Faniyi David Osagbami
Image may contain: plant
English Verison
Continue after the page break